Hymn 340: Jesu, my Lord, my God, my All

Jesu Oluwa, Oba mi

  1. mf Jesu Oluwa, Ọba mi,
    Gbohùn mi nigbati mo npè,
    Gbohùn mi lati ‘bugbe Rẹ,
    Rọjo ore-ọfẹ silẹ;
    cr Oluwa mi, mo fẹràn Rẹ,
    Jẹ ki nle ma fẹràn Rẹ si.

  2. p Jesu, mo ti jafara jù,
    cr Ngo ṣe le fẹ Ọ b’o ti yẹ?
    Em’ o ṣe le gb’ ogo Rẹ ga,
    Ati ẹwà orukọ Rẹ.
    f Oluwa mi, &c.

  3. mp Jesu, kil’ o ri ninu mi,
    Ti ‘fẹ na fi pọ̀ to bayi?
    cr Ore Rẹ si mi ti pọ̀ to!
    O ta gbogbo èro mi yọ!
    f Oluwa mi, &c.

  4. f Jesu, ‘Wọ o jẹ orin mi,
    Tirẹ l’ aìya at’ ọkàn mi:
    Tirẹ ni gbogbo ini mi,
    Olugbala, ‘Wọ ni temi:
    ff Oluwa mi, mo fẹràn Rẹ,
    Jẹ ki nle ma fẹràn Rẹ si. Amin.