- f Eyi l’ ọjọ t’ Oluwa da,
O pe ‘gba na ntirẹ̀;
K’ orun k’ o yọ̀, k’ aiye k’ o yọ̀
K’ iyin yi ‘tẹ na ka.
- Loni, o jinde ‘nu okù,
Ijọba Satan tu:
‘Won mimọ́ tan ṣẹgun Rẹ̀ ka
Nwọn nsọrọ ‘yanu Rẹ̀.
- ff Hosanna si Ọba t’ a yàn,
S’ Ọmọ mimọ́ Dafid’;
mf Oluwa, jọ sọkalẹ wá
T’ Iwọ t’igbala Rẹ.
- Abukun l’ Oluwa t’ o wá
N’iṣẹ ore-ọfẹ;
T’ o wá l’ orukọ Baba Rẹ̀,
Lati gba ‘ran wa là.
- ff Hosanna li ohun goro,
L’ orin Ijọ f’ aiye,
Orin t’ oke ọrun lọhun
Yio dùn jù bẹ lọ. Amin.