- mf Ifẹ ọrun, o ti dùn to!
Gbawo ni ngo ri t’ọkàn mi,
Y’o kun fun kìki rẹ?
cr Ọkàn mi npongbẹ lati mọ̀
Rirì ifẹ ìrapada;
Ifẹ Kristi si mi.
- f Ifẹ Rẹ̀ n’ ipa jù iku;
Ọrọ̀ Rẹ̀ awamaridi!
Awọn Angẹl papa
Wá ijinlẹ ifẹ yi ti;
di Nwọn kò le mọ̀ iyanu na,
Giga at’ ìbú rẹ̀
- p Ọlọrun nikan l’o le mọ̀,
Iba jẹ tàn ka ‘lẹ loni;
L’ ọkàn okuta yi!
cr Ifẹ nikan ni mo ntọrọ,
K’o jẹ ipin mi Oluwa;
K’ ẹbun yi jẹ temi.
- mf Emi iba le joko lai,
Bi Maria, lẹsẹ Jesu;
K’ eyi jẹ ayọ̀ mi:
K’o j’ aniyan at’ifẹ mi,
K’o sì j’ọrun fun mi laiye,
Lati ma gbohùn Rẹ. Amin.