- mf Ọkàn mi, Oluwa ni,
Jesu rẹ ni, gbọrọ Rẹ̀;
Jesu nsọ, O mba ọ sọ,
p Pe, ẹ̀lẹṣẹ, ‘wọ fẹ Mi?
- mf ‘Gbat’ a dè ọ, Mo da ọ,
O gb’ ọgbẹ, Mo wò ọ sàn;
‘Gb’ o ṣako, Mo mu ọ bọ̀;
Mo s’ okùn rẹ d’ imọlẹ̀.
- Kikẹ iya ha le mọ
Si ọmọ rẹ̀ ti o bi?
di Lotitọ o lè gbagbe,
cr Ṣugbọn Em’ o ranti
- mf Ifẹ t’Emi ki yẹ̀ lai,
O ga rekọja ọrun;
O si jìn jù okun lọ,
f Ifẹ alailẹgbẹ ni.
- cr ‘Wọ fẹrẹ̀ r’ogo Mi na,
‘Gb’ iṣẹ ore-ọfẹ tan;
‘Wọ o ba Mi gunwa pọ̀;
p Wí, ẹlẹṣẹ, ‘wọ fẹ Mi?
- mp Olori aroye mi
Ni pe ifẹ mi tutu;
cr Ṣugbọn mo fẹ Ọ Jesu,
f A! mba le fẹ Ọ ju yi! Amin.