- f Awa kọ orin ifẹ Rẹ,
Ọbangiji Ọba Ogo:
Kò s’ohun ti lalàṣi Rẹ,
Ọla Rẹ kò si nipẹkun.
- f N’nu ifẹ l’o ṣ’ẹda aiye,
O da enia sinu rẹ̀;
Lati ma ṣ’akoso gbogbo;
ff Ẹ kọrin ‘fẹ Ẹlẹda wa.
- f Lojojumọ l’O ntọju wa,
O si mbọ́, O si nṣikẹ wa;
Bẹni mò gbà nkan lọwọ wa,
ff Kọrin ‘yin s’onibu ọrẹ.
- p O ri wa ninu òkunkun,
Pe, a kò mọ̀ ojubọ rẹ̀;
N’ifẹ O fi ọna hàn wa;
ff Ẹ kọrin ifẹ Olore!
- N’ ifẹ O fi Jesu fun wa,
Ọmọbibi Rẹ̀ kanṣoṣo;
p O wa rà wa lọwọ ẹ̀ṣẹ;
ff A yin ‘fẹ Rẹ Olugbala!
- Ifẹ Rẹ̀ ran ọ̀rọ Rẹ̀ wá,
Ifẹ Rẹ̀ l’o ṣi wa leti,
Ifẹ Rẹ sì mu wa duro;
ff Ẹ kọrin ore-ọfẹ Rẹ̀.
- Gbogbo ẹda kun fun ‘fẹ Rẹ,
Oluwa wa, Ọba aiye;
ff Gbogbo agbaiye, ẹ gberin,
Orin ifẹ Ọlọrun wa. Amin.