- mf ‘Gbat aiye yi ba kọja,
Ti orùn rẹ̀ ba si wọ̀,
Ti a ba wọ̀ ‘nu ogo,
T’ a bojuwò ẹ̀hin wa;
f ‘Gbana, Oluwa, ngo mọ;
di Bi gbese mi ti pọ̀ to.
- f ‘Gba mo ba de ‘b’ itẹ Rẹ,
L’ẹwà ti kì ṣe t’emi;
‘Gba mo ri Ọ b’o ti ri,
Ti mo fẹ Ọ l’ afẹtan;
‘Gbana Oluwa, ngo mọ̀
di Bi gbese mi ti pọ to.
- f ‘Gba mba ngbọ́ orin ọrun,
Ti ndún bi ohùn ará,
Bi iró omi pupo:
p T’ o si ndún b’ ohùn dùru;
mf ‘Gbana Oluwa, ngo mọ̀
di Bi gbese mi ti pọ to.
- mp Oluwa, jọ, jẹ k’a ri
Ojiji Rẹ l’aiye yi:
p K’a mọ̀ adùn dariji,
Pẹlu iranwọ Ẹmi:
cr Ki ntilẹ̀ mọ̀ l’aiye yi,
Diẹ ninu gbèse mi.
- mf Ore-ọfẹ l’ o yàn mi,
L’ o yọ mi ninu ewu;
p Jesu l’Olugbala mi,
Ẹmi sọ mi di mimọ́,
cr Kọ mi, ki nfi hàn l’aiye,
Bi gbese mi ti pọ to ! Amin.