mf Jesu Oluwa, a fẹ Ọ, ‘Tori gbogbo ẹbùn Nt’ ọwọ Rẹ dà lat’ okè wa, B’ ìri si gbogb’ aiye. A yìn Ọ nitori wọnyi; K’ iṣe fun wọn nikan, Ni awọn ọmọ-ọdọ Rẹ, Ṣe ngbàurà si Ọ.
p Awa fẹ Ọ, olugbala, ‘Tori ‘gba t’ a ṣako; Iwọ pe ọkàn wa pada, Lati t’ ọna iye. ‘Gba t’ a wà ninu òkunkun, T’ a rì ninu ẹ̀ṣẹ: cr ‘Wọ ran imọlẹ Rẹ si wa, Lati f’ ona han wa.
f Baba ọrun, awa fẹ Ọ, Nitori ‘Wọ fẹ wa; Wọ ran Ọmọ Rẹ lati kú, Ki awa lè n’ iyè, mp ‘Gbat’ a wà labẹ binu Rẹ ‘Wọ fun wa n’ ireti: cr Bi ẹ̀ṣẹ t’ a da ti pọ̀ to Bẹ l’o dariji wa. Amin.