- mf Orukọ kan mbẹ ti mo fẹ
Mo fẹ ma kọrin rẹ̀;
Iró didun ni l’eti mi,
Orukọ didun ni.
- O sọ ifẹ Olugbala,
p T’o kú lati rà mi;
O sọ t’ẹjẹ Rẹ̀ ‘yebiye
Etutu f’ ẹlẹṣẹ.
- cr O sọ ti iyọ́nu Baba,
Ti o ni s’ Ọmọ Rẹ̀;
O m’ ara mi yá, lati la
Aginjui aiye ja.
- mf Jesu, Orukọ ti mo fẹ,
T’o si dùn l’eti mi;
Kò s’ ẹni mimọ́ kan l’ aiye,
T’o mọ̀ b’ o ti pọ̀ to.
- cr Orukọ yi j’orùn didùn,
L’ọnà egún t’ a nrìn;
Yio tun ọnà yangi ṣe,
T’o lọ s’ọd’ Ọlọrun.
- f Nibẹ pẹlu awọn mimọ́,
Ti nwọn bọ́ nin’ ẹṣẹ,
Emi o kọrin titun ni,
T’ifẹ Jesu si mi. Amin.