Hymn 333: Love divine, all loves excelling

Ife orun, alailegbe

  1. f Ifẹ orun, alailẹgbẹ,
    Ayọ̀ ọrun, sọkalẹ;
    Fi ọkàn wa ṣe ‘bugbe Rẹ;
    Ṣe aṣetan anu Rẹ;
    p Jesu, iwọ ni alanu,
    Iwọ l’onibu ifẹ;
    cr Fi igbala Rẹ bẹ̀ wa wò,
    M’ ọkàn ẹ̀ru wa duro.

  2. mf Wá, Olodumare, gbà wa,
    Fun wa l’ ore-ọfẹ Rẹ;
    Lojiji ni k’ o pada wa,
    Má si fi wa silẹ mọ:
    f Iwọ l’a o ma yìn titi,
    Bi nwọn ti nṣe ni ọrun;
    Iyìn wa kì yio l’ opin,
    A o ṣogo n’nu ‘fẹ Rẹ.

  3. cr Ṣasepe awa ẹda Rẹ,
    Jẹ ka wà lailabawọn;
    K’ a ri titobi ‘gbala Rẹ,
    Li aritan ninu Rẹ.
    ff Mu wa l’ a t’ ogo de ogo
    Titi de ibugbe wa:
    Titi awa o fi wolẹ̀,
    N’ iyanu ifẹ, ìyin. Amin.