Hymn 332: My blessed Saviour, is Thy love

Olugbala mi, ife Re

  1. mf Olugbala mi, ifẹ Rẹ
    Ha tobi bẹ si mi?
    Wo, mo f’ ifẹ mi, ọkàn mi,
    At’ aiya mi fun Ọ.

  2. Mo fẹ Ọ nitori ‘toye,
    Ti mo ri ninu Rẹ;
    p Mo fẹ Ọ nitori ìya,
    T’ o f’ ara dà fun mi.

  3. f Bi Iwọ ti jẹ Ọlọrun,
    T’ a f’ ogo de l’ ade;
    di Iwọ kò kọ̀ àwọ enia,
    T’ o kun fun iyọnu.

  4. p ‘Wọ jẹ k’ a bi Ọ l’ enia,
    Ṣugbọn ‘Wọ kò l’ẹ̀ṣẹ;
    cr K’ awa lè ri b’ Iwọ ti ri,
    K’ a lè ṣe b’ O ti ṣe.

  5. f K’ a dabi Rẹ ninu ifẹ,
    L’ ẹwà ìwa mimọ́;
    cr B’ a ti nwoju Rẹ, k’ a ma lọ,
    L’ at’ ogo de ogo. Amin.