- f B’ orukọ Jesu ti dùn to
Leti olugbagbọ́!
O tan banujẹ on ọgbẹ,
O le ẹ̀ru rẹ̀ lọ.
- mf O wo ọkàn t’o gbọgbẹ sàn,
O mu aiya balẹ;
Manna ni fun ọkan ebi,
Isimi f’alarẹ̀.
- f Apata ti mo kọle le,
Ibi isadi mi:
Ile iṣura mi t’o kún,
F’ọpọ̀ ore-ọfẹ.
- cr Jesu, Ọkọ mi, Ọrẹ mi,
Woli mi, Ọba mi:
Alufa mi, Ọna, Iye,
Gba orin iyin mi.
- p Ailera l’ agbara ‘nu mi,
Tutu si l’ ero mi;
Gba mo ba ri Ọ b’ O ti ri,
Ngo yìn Ọ b’o ti yẹ.
- f Tit’ igbana ni ohùn mi,
Y’o ma ròhin ‘fẹ Rẹ;
di Nigba iku, k’ Orukọ Rẹ
p F’ itura f’ ọkàn mi. Amin.