Hymn 330: Jesus, the very thought of thee

Jesu, kiki ironu Re

  1. mf Jesu, kìki ironu Rẹ,
    Fi ayọ̀ kún ọkàn;
    Ṣugbọn k’a ri Ọ l’o dùn jù,
    K’a simi lọdọ Rẹ.

  2. f Ẹnu kò sọ, eti kò gbọ,
    Ko ti ọkàn wá ri;
    Okọ t’o sọ̀wọn, t’o dun bi
    Ti Jesu Oluwa.

  3. p Ireti ọkàn ti nkanu,
    Olore ẹlẹṣẹ;
    cr O ṣeun f’ awọn ti nwa Ọ,
    f Awọn t’o ri Ọ yọ̀.

  4. f Ayọ̀ wọn, ẹnu kò le sọ,
    Ẹda kò le rohin;
    Ifẹ Jesu, b’o ti pọ̀ to,
    Awọn Tirẹ̀ l’o mọ̀.

  5. f Jesu, ‘Wọ ma jẹ ayọ̀ wa,
    ‘Wọ sa ni ère wa;
    Ma jẹ ogo wa nisiyi,
    Ati titi lailai. Amin.