- Ọjọ mẹfa t’iṣẹ kọja,
Ọkan t’ isimi si bẹrẹ;
Wá, ọkàn mi si ‘simi rẹ,
Yọ̀ s’ ọjọ t’ Ọlọrun busi.
- Ki ‘ronu at’ ọpẹ wa nde,
Bi ẹbọ turaro s’ ọrun;
K’ o le fà inu dìdùn wà’
T’ o jẹ t’ ẹni t’ o mọ̀ nikan.
- Ibalẹ aiya ọrun yi,
L’ ẹri isimi t’ o l’ogo;
T’ o wà fun enia mimọ́
p Opin aniyan at’ aisàn.
- f Ọlọrun, a yọ̀ si ‘ṣẹ Rẹ,
L’oniruru t’ ogbó t’ ọtun;
A fi ‘yin rò anu t’ o lọ,
A ni ‘reti s’eyi ti mbọ.
- F’ oni sisin mimọ jalẹ,
K’o si ṣe inu didun si;
f B’ o ti dun lati l’ ọjọ yi
Nireti ọkan ailopin? Amin.