Hymn 329: Thee will I love, my Strength, my ower

Ngo feran Re, ‘wo odi mi

  1. f Ngo fẹran Rẹ, ‘wọ odi mi:
    Ngo fẹran Rẹ, ‘wọ ayọ mi:
    Ngo fẹran Rẹ, patapata,
    Ngo fẹran Rẹ, tor’ iṣẹ Rẹ,
    cr Ngo fẹran Rẹ, tit’ọkàn mi,
    Y’o fi kun fun ifẹ rere.

  2. mf ‘Wọ Orùn mi, gba ọpẹ mi,
    Fun ‘mọlẹ Rẹ t’o fi fun mi;
    Gba ọpẹ mi, ‘wọ l’o gbà mi
    Lọwọ awọn ti nṣọta mi;
    f Gbà ọpẹ mi, fun ohùn Rẹ
    T’o mu mi yọ̀ lọpọlọpọ.

  3. mf N’nu ire-ije mi laiye,
    Ma ṣe alabojuto mi;
    cr Fi agbara fun ẹsẹ mi,
    Ki nle t’ẹsẹ m’ọna rere;
    ff Ki mba le f’ipa mi gbogbo,
    F’ orukọ Rẹ t’o l’ogo hàn.

  4. f Ngo fẹran Rẹ, ‘Wọ ade mi,
    Ngo fẹran Rẹ, Oluwa mi:
    di Ngo fẹran Rẹ nigbagbogbo,
    L’ọjọ ibi, l’ọjọ ire,
    p Gbati ọjọ iku ba de,
    f Ngo fẹran Rẹ titi lailai. Amin.