- mf A ba le n’igbagbọ àye,
B’o ti wù k’ọta pọ̀;
Igbagbọ ti kò jẹ mira
Fun aini at’ òṣi.
- p Igbagbọ ti kó jẹ rahùn
L’abẹ ibawi Rẹ;
cr Ṣugbọn ti nsimi l’Ọlọrun,
Nigba ibanujẹ.
- mf Igbagbọ ti ntàn siwaju,
Gbat’ ìji ‘pọnju de;
Ti kò si jẹ ṣiyemeji,
N’nu wahala gbogbo.
- Igbagbọ ti ngb’ọ̀na toro,
p Titi ẹmi o pin;
cr Ti y’o si f’imọlẹ ọrun,
Tàn akete iku.
- mf Jesu f’ igbagbọ yi fun mi:
Njẹ, b’o ti wù k’o ri,
cr Lat’ aiye yilọ ngo l’ayọ
Ilu ọrun rere. Amin.