Hymn 327: My hope is built on nothing less

Igbagbo mi duro, l’ori

  1. f Igbagbọ mi duro, l’ori
    Ẹjẹ at’ ododo Jesu;
    di Nkò jẹ gbẹkẹlẹ ohun kan,
    cr Lẹhin orukọ nla Jesu:
    ff Mo duro le Krist’ Apata,
    Ilẹ miran, iyanrìn ni.

  2. mf B’ ire-ije mi tilẹ̀ gùn,
    Or’-ọfẹ Rẹ̀ kò yipada;
    B’ o ti wù k’ijì na le to,
    Idakọ̀ró mi kò ni yẹ̀:
    ff Mo duro le Krist’ Apata,
    Ilẹ miran, iyanrìn ni.

  3. f Majẹmu ati ẹjẹ Rẹ̀,
    L’em’ o rọ̀mọ́ b’ ikunmi de.
    di Gbati ko s’atilẹhin mọ,
    f O jẹ ireti nla fun mi:
    ff Mo duro le Krist’ Apata,
    Ilẹ miran, iyanrìn ni.

  4. f Gbat’ipè kẹhin ba si dún,
    mp A ! mba le wà ninu Jesu,
    cr Ki nwọ̀ ododo Rẹ̀ nikan,
    Ki nduro niwaju Rẹ̀ nikan,
    ff Mo duro le Krist’ Apata,
    Ilẹ miran, iyanrìn ni. Amin.