- mp Ọna àra l’Ọlọrun wa,
Ngbà ṣiṣẹ Rẹ̀ l’aiye;
f A nri pasẹ Rẹ̀ l’or’ okun,
O ngun ìgbi l’ẹṣin.
- mp Ọna Rẹ̀ ẹnikan kò mọ̀,
Awamaridi ni;
cr O pa iṣẹ ijinlẹ mọ,
O sì nṣe bi Ọba.
- mp Mà bẹru mọ, ẹnyin mimọ,
Ọrun t’o ṣù bẹ nì,
cr O kùn fun anu: y’o rọ;jo
Ibukun s’ori nyin.
- mp Maṣe da Oluwa l’ẹjọ,
Ṣugbọn gbẹkẹ rẹ le;
cr ‘Gbati o rò pe o binu,
Inu Rẹ̀ dùn si ọ.
- mf Isẹ Rẹ̀ fẹrẹ yé wa na,
Y’o ma hàn siwaju
Bi o tilẹ korò l’oni,
O mbọ̀ wa dùn l’ọla.
- Afọju ni alaigbagbọ,
Kò mọ̀ ‘ṣẹ Ọlọrun;
f Ọlọrun ni Olutumọ̀,
Y’o m’ọna Rẹ̀ ye ni. Amin.