mp Ọm’ Ọlọrun a kò ri Ọ, Gba t’ o wá s’ aiye iku yi; Awa kò ri ibugbe Rẹ, Ni Nasareti ti a gàn; f Ṣugbọn a gbagbọ p’ ẹsẹ̀ Rẹ Ti tẹ ita rẹ̀ kakiri.
p A kò ri Ọ lori igi, T’ enia buburu kàn Ọ mọ́; A kò gbọ igbe Rẹ, wipe, “Dariji wọn, tor’ aimọ̀ wọn.” f Sibẹ, a gbagbọ pe, ‘ku Rẹ Mì aiye, o si m’ orùn ṣu.
mf A kò duro leti boji, Nibiti a gbe tẹ́ Ọ si; A kò joko ‘nu yará nì, A kò ri Ọ loju ọna. f Ṣugbọn a gbagbọ p’ angẹli Wipe, “?Iwọ ti ji dide.”
mf A kò r’ awọn wọnni t’o yàn, Lati ri ‘goke-rọrun Rẹ; cr Nwọn kọ fi iyanu wòke, p Nwọn si f’ ẹrun dojubolẹe. Ṣugbọn a gbagbọ pe nwọn ri Ọ. Bi O ti noke lọ s’ọrun.
mf Iwọ njọba l’oke loni, Wọ si mbukun awọn Tirẹ; di Imọlẹ ogo Rẹ kò tàn Si aginju aiye wa yi. f Ṣugbọn, a gba ọ̀rọ Rẹ gbọ́, Jesu, Olurapada wa. Amin.