- mf Tirẹ lailai l’ awa ṣe,
Baba, Ọlọrun ifẹ;
cr Jẹ ka jẹ Tirẹ titi,
Laiye yi, ati lailai.
- f Tirẹ lailai l’ awa ṣe,
Ma tọju wa l’ aiye yi:
‘Wọ ìye, ọnà, otọ,
Tọ́ wa si ilu ọrun.
- p Tirẹ lailai; --- Abukun
L’ awọn t’ o ṣe ‘simi wọn!
cr Olugbala, Ọrẹ wa,
Gba ‘jà wa jà de opin.
- p Tirẹ lailai: --- Jesu, pa
Awọn agútan Rẹ mọ,
cr Labẹ ìṣọ rere Rẹ
Ni k’o pa gbogbo wa mọ.
- f Tirẹ lailai:--- Aina awa
Ni o jẹ aniyàn Rẹ;
O ti f’ ẹ̀ṣẹ wa ji wa,
Tọ́ wa si ibugbe Rẹ. Amin.