- mp Nihin l’ ayidà wà;
Ojò, ẹrùn, nkoja,
di Ilẹ̀ ni nyán, ti o si nṣá,
‘Tanna dada si nkú:
f Ṣugbọn ọrọ Jesu duro,
“Ngo wà pẹlu re,” ni On wi.
- mp Nihin l’ ayida wà;
L’ọnà ajò ọrun;
N’nu gbagbọ, ‘reti, at’ ẹrù,
N’nu ‘fẹ s’ Ọlọrun wa:
di A nṣaika ọrọ yi si pọ!
“Ngo wà pẹlu re,” ni On wi.
- mp Nihin l’ ayida wà;
cr Sugbọn l’ arin eyi,
L’ arin ayidayid’ aiye,
f Ọkan wà ti ki yi;
ff Ọrọ Jehofa ki pada;
“Ngo wà pẹlu re,” ni On wi.
- mp Ọnà alafia:
Immanuẹli wa;
ff Majẹmu ti ore-ọfẹ,
Lai nwọn ki yipada;
cr “Nki yìpada,” l’ ọrọ Baba,
“Mo wà pẹlu re,” ni On wi. Amin.