mp Mo gbohun Jesu t’ o wipe, cr “Wá simi lọdọ Mi: Gbe ori rẹ, ‘wọ alarẹ̀, Le okan aiya Mi.” p Nin’ arẹ̀ on ibinujẹ, Ni mo tọ̀ Jesu wá, cr O jẹ ib’ isimi fun mi, f O si mu ‘nu mi dùn.
mp Mo gbohun Jesu t’o wipe, cr “Iwọ ti ongbẹ ngbẹ, Ngo f’ omi ‘yè fun ọ, lọfẹ, Bẹrẹ, mu, k’ o si yè.” p Mo tọ Jesu wá, mo si mu cr Ninu omi ‘ye nà; Ọkàn mi tutu, o sọji, f Mo d’ alayè ninu Rẹ̀.
p Mo gbohun Jesu t’o wipe, cr “Mọlẹ aiye l’ Emi; Wò mi, Emi ni orùn rẹ, Ọjọ rẹ y’o dara.” p Mo wo Jesu, emi si ri, cr B’ Orùn ododo mi. f Ninu ‘mọlẹ yi l’ em’ o rìn, di Tit’ ajò mi y’o pin. Amin.