mf Nipa ifẹ Olugbala, Ki y’o si nkan; Ojurere Rẹ̀ ki pada, Ki y’o si nkan. p Ọwọ́n l’ ẹjẹ t’ o wò wa sàn; Pipe l’ edidi or’ọfẹ; f Agbara l’ọwọ t’o gba ni; Kò lè si nkan.
p Bi a wà ninu ipọnju, f Ki y’o si nkan: Igbala kikun ni tiwa, Ki y’o si nkan; cr Igbẹkẹle Ọlọrun dùn; Gbigbe inu Kristi l’ erè; Ẹmi si nsọ wa di mimọ́; Ko le si nkan.
f Ọjọ ọla yio dara, Ki y’o si nkan, cr ‘Gbagbọ lè kọrin n’ ipọnju, Ki y’o si nkan. mf A gbẹkẹle ‘fẹ Baba wa; Jesu nfun wa l’ohun gbogbo; di Ni yiye tabi ni kikú, f Kò lè si nkan. Amin.