- f ‘Gba mo lè ka oyè mi re,
Ni ibugbe l’ oke;
Mo dagbere f’ ẹ̀ru gbogbo,
Mo n’ omije mi nù.
- B’ aiye kojuja s’ ọkàn mi,
T’ a nsọ ọ̀kọ si i;
‘Gbana mo le rín Satani,
Ki nsì jẹju k’ aiye.
- K’ aniyàn de b’ ikun omi,
f K’ iji banujẹ jà;
ki nsà de ‘lẹ alafia,
Ọlọrun, gbogbo mi,
- f Nibẹ l’ ọkàn mi y’ o luwẹ,
N’nu òkun isimi;
Kò si wahala t’o lè de,
S’ ibalẹ aiya mi. Amin.