- f Nigbawo Olugbala mi,
L’ emi o rì Ọ jẹ?
N’ isimi t’ o ni ibukun,
Laisi ‘boju larin.
- mf Ran mi lọwọ n’ irinkiri,
L’ aiye aniyan yi;
Ṣe mi ki nfi ‘fẹ gbadura
Si gba adura mi.
- mf Da mi si, Baba, da mi si,
Mo f’ara mi fun Ọ;
Gbà ohun gbogbo ti mo ni,
Si f’ara Rẹ fun mi,
- Ẹmi rẹ, Baba, fifun mì,
K’ o lè ma pẹlu mi;
f K’ o ṣe imọlẹ ẹsẹ̀ mi
ff S’ isimi ailopìn. Amin.