Hymn 319: Jesus Saviour is my Shepherd

Jesu l’ Olusagutan mi

  1. f Jesu l’ Oluṣagutan mi,
    Njẹ k’ ibẹru lọ jina:
    Lọwọ kiniun at’ ẹkùn,
    Lọwọ ẹranko ibi,
    Yio ṣọ agutan Tirẹ̀,
    Jesu y’ o pa Tirẹ̀ mọ.

  2. Nigb’ ọta fẹ lati mu mi,
    On ni: Agutan mi ni,
    p O sì ku, lati gba wa là;
    Jesu ifẹ kil’ eyi?
    Iṣẹgun ni ọnà Tirẹ̀,
    Ko s’ ohun t’ o lè ṣe e.

  3. Lọ̀na ìye l’ o ndari mi,
    Let’ iṣàn t’o nṣàn pẹlẹ́;
    Ninu oko tutu yọ̀yọ,
    Nib’ ewe oró ki hù,
    Nibẹ ni mo gbohun Jesu,
    Nibẹ l’ o m’ ọkàn mi yọ̀.

  4. p Gbà mo ba nlọ s’ isà okú,
    B’ ẹ̀ru tilẹ̀ wà l’ ọnà,
    Emi kì o bẹrukẹrù,
    Tor’ Oluṣagutan wà;
    f ‘Gba mo r’ ọgọ at’ ọpa Rẹ̀,
    Mo mọ̀ p’ agutan Rẹ̀ yọ. Amin.