- mf L’ọ̀na gbogbo t’ Oluwa yàn,
Ajo mi l’ em’ o tọ̀;
f Má da mì ro, ẹnyin mimọ́,
Emi o ba nyin lọ.
- Bi Jesu nlọ ninu ina,
Emi o tọ lẹhin:
f Má da mi ro, l’ emi o ke,
B’ aiye d’ ojukọ mi.
- Ninu isìn at’ idanwo,
Em’ o lọ l’ aṣẹ Rẹ:
f Má da mi ro, emi o lọ,
S’ ilẹ Emmanuẹl.
- ‘Gba Olugbala mi ba pè,
Sibẹ, k’ igbe mi jẹ,
Má da mi ro, ikú ma bọ̀,
Ngo ba ọ lọ l’ ayọ. Amin.