f Ohun ogo Rẹ l’a nrohin, Sion, ti Ọlọrun wa: Ọrọ ẹnit’ a kò lè yẹ̀, Ṣe ọ yẹ fun bugbe Rẹ̀. L’ori apat’ aiyeraiye, Kini lè mi ‘simi rẹ? A f’ odi ‘gbala yi ọ ká, K’ o lè ma rín ọta rẹ.
mf Wo! Ipadò omi iyè, Nt’ifẹ Ọlọrun sun wa, O to fun gbogbo ọmọ Rẹ̀, Ẹru aini kò si mọ; Tal’ o lè rẹ̀, ‘gba odo na Ba nṣàn t’o lè pongbẹ rẹ̀? Or’ọfẹ Olodumare Kì yẹ̀ lat’ irandiran.
cr Ara Sion alabukun, T’ a f’ẹjẹ Oluwa wẹ̀; Jesu ti nwọn ti ngbẹkẹle, Sọ wọn d’ ọba, woli Rẹ̀. p Ṣiṣa l’ohun afẹ aiye, Pẹlu ogo asa rẹ̀, f Iṣura totọ at’ ayò, Kik’ ọmọ Sion l’ o mọ. Amin.