Hymn 316: There is a fountain filled with blood

Isun kan wa t’ o kun f’ eje

  1. mf Isun kan wà t’ o kun f’ ẹ̀jẹ,
    To ti ‘ha Jesu yọ;
    Ẹlẹṣẹ mokùn ninu rẹ̀,
    O bọ ninu ẹbi.

  2. mp ‘Gba mo f’ igbagbọ r’ isun na,
    Ti nṣàn fun ẹ̀jẹ Rẹ̀,
    Irapada d’ orin fun mi,
    Ti ngo ma kọ titi.

  3. f Orin t’o dùn ju eyi lọ,
    Li emi o ma kọ;
    p Gbat’ akololo ahọn yi
    Ba dakẹ ni boji.

  4. mf Mo gbagbọ p’ O pese fun mi
    (Bi mo tilẹ ss’àiyẹ),
    Ẹbun ọ̀fẹ t’ a f’ẹjẹ rà,
    Ati durù wura.

  5. cr Durù t’ a tọw’ Ọlọrun ṣe,
    Ti kò ni bajẹ lai;
    Ti ao ma fi yìn Baba wa,
    Orukọ Rẹ̀ nikan. Amin.