- Jesu, Olugbala, wò mi,
p Arẹ̀ mu mi, ara nni mi;
cr Mo de lati gb’ ara le Ọ;
‘ Wọ ‘simi mi.
- p Bojuwò mi, o rẹ̀ mi tan;
Irìn àjo na gùn fun mi;
Mo nwa ‘ranwọ agbara Rẹ,
‘Wọ Ipà mi.
- p Idamu bá mi l’ọna mi,
cr Oru ṣokùn, ìji sì nfẹ́,
Tàn imọlẹ si ọna mi,
‘Wọ ‘Mọlẹ mi.
- Gba Satani ba tafà rẹ̀,
Wọ ni mo nwò; nkò bẹ̀ru mọ;
Agbelebu Rẹ l’abò mi,
‘Wọ Alafia mi.
- Mo nikan wà leti Jordan,
Ninu ‘waiya-‘jà, jelo nì:
‘Wọ kì yio jẹ k’emi rì;
‘Wọ Iye mi.
- Gbogbo aini, ‘Wọ o fun mi
Titi d’opin; l’ọnakọna;
Ni ‘yè, ni ‘ku, titi lailai,
‘Wọ Gbogbo mi. Amin.