Hymn 313: My faith looks up to Thee

Igbagbo mi wo O

  1. f Igbagbọ mi wò Ọ,
    Iwọ Ọdagutan,
    Olugbala:
    p Jọ gbọ adura mi,
    M’ẹ̀ṣẹ mi gbogbo lọ,
    cr K’ emi lat’ oni lọ
    Si jẹ Tirẹ.

  2. mf Ki ore-ọfẹ Rẹ
    F’ilera f’ọkàn mi.
    Mu mi tara:
    p B’ Iwọ tikú fun mi,
    cr A ! k’ifẹ mi si Ọ,
    K’o ma gbona titi;
    B’ina iye.

  3. p ‘Gba mo nrìn l’okunkun,
    Ninu ibinujẹ;
    cr Ṣ’ amọna mi.
    M’ okunkun lọ loni,
    Pa ‘banujẹ mi rẹ,
    Ki nma ṣako kuro
    Li ọdọ Rẹ.

  4. p Gbati aiye ba pin,
    T’odo tutu ikú
    Nṣàn lori mi;
    cr Jesu, ninu ifẹ,
    Mu k’ifoiya mi lọ,
    f Gbe mi d’oke ọrun,
    B’ọkàn t’a rà. Amin.