Hymn 312: Toss'd with rough winds, and faint with fear

N’ irumi at’ iji aiye

  1. mf N’ irumi at’ ìji aiye,
    Mo gbọ ohùn itunu kan,
    di O nsọ si mi l’eti wipe,
    p.cr Emi ni: maṣe bẹ̀ru.

  2. mp Emi l’o wẹ̀ ọkàn rẹ mọ.
    Emi l’o mu ki o riran,
    cr Emi n’iye, imọlẹ rẹ.
    Emi ni; maṣe bẹru.

  3. mf Awọn igbi omi wọnyi
    Ti f’ agbara wọn lù mi ri,
    Nwọn kò le ṣe ọ n’ibi mọ:
    Emi ni: maṣe bẹru.

  4. p Mo ti mu ago yi lẹkan,
    Wọ kò le mọ̀ kikoro rẹ̀,
    Emi ti mọ̀ bi o ti ri,
    Emi ni: maṣe bẹru.

  5. mf Mọ pe, l’or’ ẹni arùn rẹ,
    Oju Mi kò yẹ̀ l’ara rẹ.
    cr Ibukun mi wà l’ori rẹ,
    “Emi ni: maṣe bẹru.”

  6. mf Gbat’ ẹmi rẹ ba pin l’aiye,
    T’ awọn t’ọrun wá ‘pade rẹ,
    f Wọ o gbohùn kan t’o mọ̀, pe
    Emi ni: maṣe bẹ̀ru.” Amin.