Hymn 310: In some way or other the Lord will provide.

Li onakona, “Oluwa y’o pese.”

  1. mf Li ọ̀nakọnà, “Oluwa y’o pèse.”
    O le ṣ’aiṣ’ ọ̀na mi, o le ṣ’aiṣe tirẹ,
    Ṣugbọn lọnà ‘ra Rẹ̀, li On o pèse !

  2. Lakoko to yẹ, “Oluwa y’o pèse,”
    O le ṣ’ aiṣe temi, o le ṣ` aiṣe tirẹ,
    Lakoko t’ara Rẹ̀, li On o pèse !

  3. Má bẹru, tori “Oluwa y’o pèse,”
    Eyi n’ ileri Rẹ̀, kò s’ ọ̀rọ ti O sọ,
    Ti si yipada, “Oluwa o pèse.”

  4. f Yan lọ l’ aibikita, okún y’o pinya,
    O f’orin iṣẹgun ṣe ọ̀na rẹ logo,
    Ao jumọ gberin, “Oluwa y’o pèse.” Amin.