- f Bi mo ti yọ̀ lati gb’ ọrọ̀
L’ ẹnu awọn ọrẹ;
Pe, “Ni Sion ni k’ a pe si
K’ a p’ ọjọ mimọ́ mọ.”
- f Mo f’ ọnata at’ ẹkun rẹ;
Ile t’ a ṣe lọṣọ,
Ile t’ a kọ fun Ọlọrun;
Lati fi anu han.
- S’ agbala ile ayọ na,
L’ẹya mimọ́ si lọ,
Ọmọ Dafid wà lor’ ite,
O nda ẹjọ nibẹ.
- O gbọ íyin at’ igbe wa;
Bi ohùn ẹrù rè
mp Ti nya ẹ̀lẹṣẹ sib’ egbe,
A nyọ̀ ni warìrì
- K’ ibukun pẹlu ibe na
Ayọ nigbakugba;
K’ a fi ọrẹ ati ore,
F’awọn ti nsìn nibè
- Ọkàn mi bẹbẹ fun Sion
Nigbati ẹmi wà;
f Nibẹ ni ‘batan at’ ọrẹ́
At’ Olugbala wà. Amin.