Hymn 308: Safe in the arms of Jesus,

Laifoiya l’apa Jesu

  1. mp Laifoiya l’apa Jesu,
    Laifoiya laiya Rẹ̀,
    cr L’abẹ ojij’ ifẹ Rẹ̀,
    L’ọkàn mi o simi.
    p Gbọ́! Ohùn Angẹli ni,
    Orin wọn d’eti mi
    cr Lati papa ogo wá,
    Lati okun Jaspi,
    mf Laifoìya l’apa Jesu, Laifoìya laìya Rẹ̀,
    L’abẹ ojij’ ifẹ Rẹ̀, l’ ọkàn mi o simi.

  2. mp Laifoiya l’apa Jesu,
    Mo bọ lọw’ aniyàn,
    Mo bọ lọwọ idanwò,
    Ẹṣẹ kò n’ipa mọ.
    Mo bọ lọwọ ‘banujẹ,
    Mo bọ lọwọ ẹ̀ru,
    cr O kù idanwò diẹ !
    O k’ omije diẹ !
    mf Laifoìya l’apa Jesu, Laifoìya laìya Rẹ̀,
    L’abẹ ojij’ ifẹ Rẹ̀, l’ ọkàn mi o simi.

  3. mp Laifoiya l’apa Jesu,
    Jesu ti ku fun mi;
    f Apata aiyeraiye
    L’ emi o gbẹkẹle.
    mp Nihin l’ emi o duro,
    Tit’ oru y’o kọja;
    cr Titi ngo fi r’ imọlẹ,
    Ni ebute ogo.
    mf Laifoìya l’apa Jesu, Laifoìya laìya Rẹ̀,
    L’abẹ ojij’ ifẹ Rẹ̀, l’ ọkàn mi o simi. Amin.