Hymn 307: Safe in the arms of Jesus,

Lala mi po, nko ni ’simi laiye

  1. mp Lala mi pọ̀, nkò ni ‘ọimi laiye;
    Mo rìn jinna, nkò r’ ibugbe laiye,
    Nikẹhìn mo wá wọn laiya Ẹni
    T’O n’ọwọ Rẹ̀, t’O si npè alarẹ;
    cr Lọdọ Rẹ̀, mo r’ile at’ isimi:
    Mo sì di Tirẹ̀, On sì temi.

  2. mf Ire ti mo ni, lat’ ọdọ Rẹ̀ ni:
    B’ ibi ba de, o jẹ b’o ti fẹ ni;
    B’ On j’ọrẹ́ mi, mo là bi nkò ri jẹ,
    L’aisi Rẹ̀, mo tòṣi bi mo l’ọrọ̀:
    Ayida le de; ère tab’ òfo;
    O dùn mọ mi, bi ‘m’ ba sa jẹ Tirẹ̀.

  3. cr B’ayida de, mo mọ̀----On ki yidà;
    Orùn ogo ti ki ku, ti ki wọ̀;
    O nrìn lor’ awọsanma at’ iji,
    O ntanmọlẹ s’òkunkun enia Rẹ̀:
    di Gbogbo nkan le lọ, kò bà mi n’nu jẹ,
    Bi ‘m’ ba jẹ Tirẹ̀, ti On jẹ temi.

  4. mf A ! laiye, nkò mọ̀ idaji ‘fẹ Rẹ̀;
    Labọ ni mo nri, labọ ni mo nsin
    cr ‘Gbà mo ba f’oju kan loke lọhun,
    Ngo fẹran Rẹ̀ pọ̀, ngo sì yin jọjọ:
    f Ngo wi larin ẹgbẹ-orin ọrun,
    Bi mo ti jẹ Tirẹ̀, t’On jẹ temi. Amin.