- mp Oluwa Ọlọrun mi, ṣe ‘fẹ Rẹ:
Nki o mì ‘ra,
p Nkò ni dide, ki nmá ba ṣeṣi ta
Ọwọ na nù,
Ti nmu mi rọ̀ mọ̀ aiya Baba mi
Ni isimi.
- mf Ọkàn ti njijakadì, ni Kristi
Nfun l’ agbara;
p Iwaìya ija Rẹ̀ oru, ‘gbati
Kò s’ ẹnikan,
Jù Baba at’ Angẹli rere kan
Ti ntu ninu.
- mp “Baba, ‘fẹ mi kọ, Tirẹ ni k’a ṣe”
Bẹ l’Ọmọ wi,
cr K’ eyi jẹ ‘ṣiri wa larin gbogbo
Lala aiye,
p K’a le rọ̀ mọ aiya Rẹ titi lai
Ni isimi. Amin.