- f Jesu l’Oluṣagutan mi,
Ore ẹniti ki yẹ̀!
Kò s’ewu bi mo jẹ Tirẹ̀,
T’ On sì jẹ temi titi.
- f Nib’ odo omi ìye nṣàn,
Nibẹ l’o nm’ ọkàn mi lọ;
Nibiti oko tutù nhù,
L’o nf’onjẹ ọrun bọ́ mi.
- p Mo ti fi wère ṣako lọ,
cr B’ Iwọ ba wà lọdọ mi;
di Ọgọ Rẹ ati ọpa Rẹ,
f Awọn l’o ntù mi ninu.
- p Nkò bẹru ojiji iku,
cr B’ Iwọ ba wà lọdọ mi;
Ọgọ Rẹ ati ọpa Rẹ,
Awọn l’o ntù mi ninu.
- mf Iwọ tẹ̀ tabili fun mi;
Wọ d’ ororo sori mi;
A ! ayọ̀ na ha ti pọ̀ to !
Ti nt’ ọdọ Rẹ wá ba mi.
- f Bẹ, lọjọ aiye mi gbogbo,
Ore Rẹ ki o yẹ̀ lai;
Oluṣagutan, ngo yìn Ọ,
Ninu ile Rẹ titi. Amin.