- f Baba, b’ ifẹ Rẹ ni, lati
p Dù mi l’ohun aiye,
Sa jẹ ki adurà mi yi
Goke de itẹ Rẹ.
- f F’ọkàn tutu, t’ọpẹ fun mi;
Gbà mi, lọwọ kikùn;
Fun mi n’ ibukun or’ọfẹ;
Si jẹ ki nwà fun Ọ.
- f K’èro yi pe, ‘Wọ ni temi
cr Ma ba mi lọ laiye;
Pẹlu mi lọna àjo mi,
p Si ba mi d’opin rẹ̀. Amin.