APA I- Iwọ Isun imọlẹ;
Ogo ti kò l’okunkun;
Aiyeraiye, titi lai,
p Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- Kanga Iye ti nṣàn lai;
Iye ti kò l’ abawọn,
Iye t’o ni irọra,
di Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- p Olubukun, Olufẹ,
Ọmọ Rẹ mbẹ̀ Ọ loke;
Ẹmi Rẹ nradọ bò wa;
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- mf Y’ itẹ safire Rẹ ka
L’ oṣumare ogo ntàn:
p O kun fun alafia,
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- mf N’ iwaju ‘tẹ anu Rẹ
L’ awọn Angẹli npade,
p Ṣugbọn wò wa lẹsẹ Rẹ,
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- mp Iwọ ti ọkàn Rẹ nyọ́
S’ amuṣua t’ o pada,
T’O mọ̀ ‘rìn rẹ̀ lokere,
p Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- pp Ọkàn ti nwá isimi;
Ọkàn t’ ẹ̀ru ẹ̀ṣẹ npa;
B’ ọm’-ọwọ ti nke f’ọmu,
p Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- cr Gbogbo wa ni alaini
L’ ebi, l’ ongbẹ at’ arẹ̀;
Kò si ède f’ aini wa,
p Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- mf Iṣura ọpọlọpọ
Kọ l’ O kojọ bi Ọba?
Ainiye, aidiyele?
p Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- mp ‘Wọ kò da Ọmọ Rẹ si,
Ọmọ Rẹ kanṣoṣo na,
Tit’ O fi par’ iṣẹ Rẹ,
p Baba Mimọ, gbọ ti wa.
APA II- mp ‘Wọ t’O sunmọ, gb’ O nkẹdùn,
T’ O gbọ ‘gbe Rẹ̀ ikẹhin;
T’O jọwọ Rẹ̀ lati ku.
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- p Iwọ ti o le gbà ni
L’ọwọ ìji iparun,
L’ọwọ ‘boji at’ iku.
pp Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- f ‘Wọ lọw’ ọtun Ẹniti
On joko nisisiyì,
T’O gunwà bi t’ iṣaju
p Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- f Wọ t’o f’ ore de l’ade,
T’O sì gbe mọ aiya Rẹ,
On n’ Imọlẹ oju Rẹ.
p Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- f Gbogb’ ẹ̀bun meje ọrun,
Lọdọ Ẹmi meje nì
L’ okọ Olurapada.
p Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- mf L’ aṣẹ Rẹ̀ ni Ẹmi wá,
‘Mọlẹ̀ at’ ẹ̀la ahọn,
L’ okọ Olurapada.
p Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- Fun wa li akoko yi,
Lat’ inu ẹ̀bun Rẹ wá,
‘Mọlẹ, ìye, agbara.
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
- p Gbọ́ ‘gbe wa, gbọ́ aini wa;
pp Gbọ́, Ẹmi mbẹbẹ n’nu wa:
cr Gbọ́, tori Jesu nṣìpẹ.
p Baba Mimọ, gbọ ti wa. Amin.