Hymn 301: There is an eye that never sleeps

Oju kan mbe ti ki togbe

  1. mf Oju kan mbẹ ti ki togbe,
    Nigbat’ ilẹ ba ṣú;
    Eti kan si mbẹ ti kì ise,
    ‘Gbati orùn ba wọ̀.

  2. Apa kan mbẹ, ti kò lè rẹ̀,
    ‘Gba ‘pa enia pin;
    Ifẹ kan mbẹ, ti kò lè kù,
    ‘Gba ‘fẹ aiye ba kù.

  3. Oju na nwò awọn Seraf,
    Apa nà d’ọrun mu;
    Eti na kun f’orin Angẹl,
    Ifẹ na ga lokè.

  4. mp Ipa kan l’ enia lè lò,
    ‘Gbat’ ipa gbogbo pin;
    Lati ri oju at’ apa,
    Ati ifẹ nla nà.

  5. cr Ipa na ni adurà wa,
    Ti nlọ ‘waju itẹ;
    f T’o nmi ọwọ t’o s’aiye ró,
    Lati mu ‘gbala wá.

  6. mp Iwọ t’anu Rẹ tò lopin,
    T’ifẹ Rẹ kò le ku:
    f Jẹ k’ a n’ igbagbọ at’ ifẹ,
    cr K’a le ma gbadurà. Amin.