mf Lọ, l’orọ̀ kutukutu, Lọ, ni ọ̀sángangan, Lọ, ni igba aṣalẹ, Lọ, ni ọganjọ oru; Lọ, t’ iwọ t’ inu rere, Gbagbe ohun aiye, p Si kunlẹ̀ n’ iyẹwu rẹ, Gbadurà nikọkọ̀,
mf Ranti awọn t’ o fẹ ọ, At’ awọn t’ iwọ fe; Awọn t’o korira rẹ, Si gbadurà fun wọn; Lẹhin na, tọtọ ‘bukun Fun ‘wọ tikalarẹ; Ninu adurà re, ma Pe orukọ Jesu.
B’ áye ati gbadura Nikọkọ̀ kò si si, T’ọkàn rẹ fẹ gbadura, ‘Gbat’ ọrẹ́ yi ọ ka, ‘Gbana, adurà jẹjẹ Lat’ inu ọkàn rẹ Y’o de ọdọ Ọlọrun, Ọlọrun Alanu.
f Kò ọi ayọ́ kan l’aiye, T’ o si ju eyi lọ: nit’ agbara t’ a fin wa. Lati ma gbadura; p ‘Gbat’ inu rẹ ko ba dùn, Jẹ k’ ọkàn rẹ wolẹ̀; cr Ninu ayọ̀ rẹ gbogbo, Ranti or’ọfẹ rẹ. Amin.