mf Jesu, a fẹ pade, L’ ọjọ Rẹ mimọ́ yi; mf A si y’ itẹ Rẹ ka, L’ ọjọ Rẹ mimọ́ yi; ff ‘Wọ ọrẹ́ wa ọrun, Adura wa mbọ wá, mf Bojuwo ẹmí wa L’ ọjọ Rẹ mimọ́ yi.
f A kò gbọdọ lọra, L’ ọjọ Rẹ mimọ́ yi; Li ẹ̀ru a kunlẹ, L’ ọjọ Rẹ mimọ́ yi; Ma tàrò iṣe wa, K’ iwo k’ o si kọ wa, K’ a sin Ọ b’ o ti yẹ L’ ọjọ Rẹ mimọ́ yi.
A tẹti s’ ọ̀rọ Rẹ L’ ọjọ Rẹ mimọ́ yi; Bukun ọ̀rọ t’ a gbọ, L’ ọjọ Rẹ mimọ́ yi; ff Ba wa lọ ‘gba t’ a lọ, F’ ore igbala Rẹ Si aiya wa gbogbo, L’ ọjọ Rẹ mimọ́ yi. Amin.