- f Ninu gbogbo ìji ti nja,
Ninu gbogbo ìgbi ‘pọnju,
Abò kan mbẹ, ti o daju;
p O wà labe itẹ-anu.
- mf Ibi kan wà ti Jesu ndà
Ororo ayọ̀ s’ ori wa;
O dùn ju ibi gbogbo lọ;
p Itẹ̀-anu t’ a f’ẹjẹ wọ̀.
- f Ibi kan wà fun idapọ̀
Nibi ọ̀rẹ́ npade ọ̀rẹ́;
Lairi ‘ra, nipa igbagbọ,
p Nwọn y’ itẹ-anu kanna ka.
- f A ! nibo ni a ba sá si,
Nigba ‘danwo at’ ipọnju?
A ba ṣe le bori Eṣu,
p Boṣepe kò si ‘tẹ-anu?
- f A ! bi idi l’a fò sibẹ,
B’ẹnipe aiye kò si mọ,
Ọrun wa ‘pade ọkàn wa,
p Ogo si bò itẹ-anu. Amin.