- mf Ma gbadurà; Ẹmi mbẹbẹ n’nu rẹ
Fun gbogbo aini rẹ igbagbogbo.
- mp Ma gbadurà; labẹ ẹrù ẹ̀ṣẹ
Adurà nri ẹ̀jẹ Jesu ti nṣàn.
- Ma gbadurà; b’ arẹ tilẹ mu ọ,
Adurà ngbe wa s’ẹba ‘tẹ Baba,
- cr Ma gbadurà; n’nu wahala aiye,
Adurà l’o nfun ọkàn n’ isimi.
- f Ma gbadurà; b’ayọ̀ ba yi ọ ka,
cr Adurà nlù harp, o nkọrin angẹl’.
- p Ma gbadurà; b’awọn t’o fẹran ku,
cr Adurà mba wọn mu omi ìye.
- di Gbogb’ ohun aiye y’o b’aiye kọja,
mf Adurà wà titi: ma gbadurà. Amin.