- mf Bibel’ iwe aiyeraiye !
Tanui le r;idi rẹ?
Tani ;e sọ dide rẹ?
Tani le m’ opin rẹ?
- f Aṣiri Olodumare;
Ikọ Ọba ọrun;
ff Idà t’o pa oro iku;
Aworan Ọlọrun.
- mf Ọkan ni Ọ larin ọ̀pọ
Iwe aiye ‘gbani,
Iwọ l’o s’ọ̀na ìgbala
Di mimọ̀ f’ araiye.
- mf Iṣura ti Mẹtalọkan,
ff Ọba nla t’o gunwà;
Jọ, tumọ̀ ara rẹ fun mi,
Ki ‘m’ ye ṣiyemeji.
- Ki ‘m’ ṣí ọ pẹlu adurà,
Ki ‘m’ k’ ẹkọ ninu rẹ;
Iwọ Iwe Aiyeraiye
F’ ifẹ Jesu hàn mi. Amin.