Hymn 295: Father of mercies, in thy word

Baba orun, nin’ oro Re

  1. f Baba ọrun, nin’ọ̀rọ Rẹ
    Ni ogo ọrun ntàn;
    Titi lai l’a o ma yin Ọ
    Fun Bibeli mimọ.

  2. mp Ọpọ ‘tunu wà ninu rè,
    Fun ọkàn alarẹ̀;
    Gbogbo ọkàn ti ongbẹ ngbẹ,
    Nri omi iye mu.

  3. f Ninu rẹ̀ l’alafia wà,
    Ti Jesu fi fun wa;
    Iye ainipẹkun si wà,
    N’nu rẹ̀ fun wa gbogbo.

  4. mf Iba lè ma jẹ ayọ̀ mi,
    Lati ma ka titi;
    cr Ki mma ri ọgbọn titun kọ,
    N’nu rẹ̀ lojojumọ.

  5. mf Oluwa Olukọ ọrun,
    Màṣe jina si mi;
    Kọ mi lati fẹ ọ̀rọ Rẹ,
    Ki nri Jesu nibẹ. Amin.