- mf Iwe kan wa ti kika rẹ̀,
Kò ṣoro fun enia,
Ọgbọn ti awọn t’o ka nfẹ,
Ni ọkàn ti o mọ́.
- Iṣẹ gbogbo t’Ọlọrun ṣe,
L’oke, n’ilẹ; n’nu wa;
Nwọn j’ọkan ninu iwe na,
Lati f’Ọlọrun hàn.
- mf Imọlẹ oọupa l’oke,
Lat’ ọdọ orùn ni;
Bẹ l’ogo Ijọ Ọlọrun,
T’ọdọ Ọlọrun wá.
- mf Iwọ ti O jẹ ki a ri,
Ohun t’o dara yi:
Fun wa l’ọkàn lati wá Ọ,
K’a ri Ọ nibi gbogbo. Amin.