- mf Ọlọrun l’abò ẹni Rè,
Nigba iji ipọnju de;
K’ awa to ṣe àroye wa.
A! sa wó t’ on t’ iranwọ Rẹ̀,
- f B’ agbami riru mbù soke,
Ọkàn wa mbẹ l’alafia;
Nigb’ orilẹ̀ at’ etido,
Ba njaya riru omi na.
- Iwe ọ̀wọ ni, ọrọ Rẹ,
Kawọ ibinu fùfu wa:
Ọrọ Rẹ m’alafia wá,
O f’ ilera f’ọkàn are. Amin.