f Iwọ Ọrọ Ọlọrun, Ọgbọn at’ oké wa, Otọ ti kì ‘yipada, Imọlẹ aiye wa: cr Awa yìn Ọ fun ‘mọlẹ̀ T’ inu Iwe mimọ́; Fitila fun ẹsẹ wa, Ti ntàn titi aiye.
mf Oluwa l’ o f’ẹbùn yi Fun Ijọ Rẹ̀ l’ aiye; A ngbe ‘mọlẹ̀ na soke Lati tàn y’ aiye ka, Apoti wura n’iṣe, O kun fun Otitọ; Aworan Kristi si ni, Ọrọ iye totọ.
f O nfẹ lẹlẹ b’ asia, T’ a ta loju ogun; O ntàn b’ iná alore, Si okunkun aiye; Amọna enia ni, p Ni wahala gbogbo, Nin’ arin omi aiye, cr O ntọ́ wa sọdọ Krist.
f Olugbala, ṣe ‘jọ Rẹ, Ni fitila wura; Lati tan imọlẹ Rẹ, Bi aiye igbani; Kọ́ awọn ti o ṣako, Lati lo ‘mọlẹ yi, Tit’ okùn aiye y’o pin, Ti nwọn o r’oju Rẹ. Amin.