- mf Jesu, ọrọ Rẹ, yè,
O si ntọ́ ‘ṣisẹ wa;
Ẹnit’ o ba gbàgbọ,
Y’o l’ayọ on ‘mọlẹ.
- p Nigb’ọta sunmọ wa,
Ọrọ Rẹ l’odi wa;
Ọrọ itunu ni,
Ikọ̀ igbala ni.
- p B’igbi at’okùnkùn
Tilẹ bò wa mọlẹ;
cr ‘Mọlẹ rẹ̀ y’o tọ́ wa,
Y’o si dabobò wa.
- mf Tani le sọ ayọ,
T’o le kà iṣura,
Ti ọrọ Rẹ nfi fun
Ọkàn onirẹlẹ?
- Ọrọ anu, o nfi
Lera fun alaye,
Ọrọ iye, o nfi
p Itunu f’ẹni nku.
- mf Awa iba le mọ̀
Ẹkọ ti o nkọni,
Ki a ba le fẹ Ọ,
K’ a si le sunmọ Ọ. Amin.